Ìlú ti Bahia jẹ́ ìlú ti èyìàn dúdú pọ̀ jùlọ ni agbaye lẹ́hìn Afirika



 

Orúkọ tèmi ni Olúk agba Adelson de Brito ti gbogbo yin mọ̀ si Mawo Adelson

Emi ni Olùkọ́ Èdè àti Àà Yorùbá-Nàgó.  

Mo si tún jẹ́ olori Ẹ̀sin Ibilẹ̀ Òrìà ati Vodun ní ìlú Salvador, ti olú-ìlú ipinlẹ̀ Bahia.

O ti pe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún bayii ti owo ẹrú ti bẹrẹ jakejado agbaye, tawọn orilẹede agbaye si ti se ọpọ eto lati se ayẹyẹ náà.

Fún àpẹẹrẹ, ni oşù keji ọdún ní orílẹ̀-èdè Amẹ́rika (USA) jẹ́ àsìkò ti wọn máa şe ìrántí ìtàn àwọn adúláwọ̀ ti o jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́rika.

Brasili tíi ṣé orílẹ̀-èdè kéji ti àwọn aláwọ̀ dúdú pọ̀ sí jùlọ àgbáyé lẹ́hìn orilẹ̀-èdè Naijiria.

Ni ode oni ni ìlú Brasili, ani bi ọgọ́ta millionu àwon ènìyàn dúdú tojẹ́ ọmọ ọmọ àwọn ẹrú tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n, kosi ohun kankan ti ijọba maa şe fún ìrántí ìtàn àwọn adúláwọ̀ ti o jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè yìí.

Salvador lokọ́kọ́ jẹ́ Olú ìlú Brasili lati Ọdún 1549 titi di dún 1763, elekeji ni Ìlú Rio de Janeiro, lati dún 1763 titi di 1960, lẹ́hìn igbana, Brasilia titi di asiko yìí.

             Ìlú Salvador jẹ́ dida silẹ̀ ni Ọjọ́ 29, Oṣù Kẹta, Ọdún 1549, gẹgẹbi Òlu ìlú Brasili ni Aiye àwn oyinbo amunisin Prtugi.

  Wọn mú Ìlú yìí gẹgẹbi Olú Ìlú nitori osúnmọ́ eti òkun ti anpe ni Bahia de Todos os Santos.

e o mọ̀ wípè ni aye atijọ́, làkókò oko ẹrú ni ìlú yìí, àwọn ọmọ káàrò-oòjíire lò èdè kanna fún ibaraninsọ̀rọ̀ laarin ara wọn?

e o mọ̀ wípè pè nitori wn a n pé “Ànàgó” abi Nàgó, èdè ti wọn lò tún a pè “èdè Ànàgó” abi “Nàgó”?

Ó se pàtàkì láti mọ díẹ̀ nípa ìtàn àwọn ènìyàn Ànàgó ni Ìlú yìí.

 Ìdí èyí ni pé yóò jẹ́ ohun ìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó yẹ ní mímọ̀ nínú ìtàn aláwọ̀ dúdú ti wọn ń ngbe ni ìlú yìí.

Fún ìdí pàtàkì yìí, n ó ò pín akosilẹ̀ yìí si ọ̀nà mẹ́tà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

1.    Àwọn imale Nàgó àti ọ̀rọ̀ oṣelú ti ìlú Salvador làkókò oko ẹrú

2.    Àwọn oníṣòwò Nàgó;

3.    Àwọn ẹsin ibilẹ̀ Ànàgó:  àwọn oloorìṣà àti ẹsin ibilẹ̀ Vodun

 

Ni osẹ to n bọ̀ a maa kọ̀ yin nipa Àwọn imale Nàgó àti ọ̀rọ̀ oṣelú làkókò oko ẹrú ni ìlú yìí

 

O dabọ!

Tradução

A Cidade da Bahia é a Cidade mais preta do mundo fora da África

Meu nome é Adelson de Brito, mais conhecido como Mawo Adelson

Sou professor de Língua e Cultura Ioruba-Nàgó.

Também sou Sacerdote da Igreja tradicional Orixá e Vodun em Salvador, capital do Estado da Bahia.

Já se passaram quase 500 anos desde que o tráfico de escravos começou em todo o mundo, e muitos países ao redor do mundo planejam eventos para marcar a data.

Por exemplo, o mês de fevereiro nos Estados Unidos da América (EUA) é uma época para comemorar a história dos negros americanos.

O Brasil é o segundo país mais negro do mundo, depois da Nigéria.

Hoje, no Brasil, cerca de 60 milhões de negros são descendentes de escravos, mas nem assim o governo faz qualquer evento para comemorar a história dos negros.

Salvador foi a capital do Brasil de 1549 a 1763, a segunda foi o Rio de Janeiro, de 1763 a 1960, e depois Brasília, até hoje

 Salvador foi fundada em 29 de março de 1549, como capital do Brasil na colônia portuguesa.

  A cidade foi considerada a capital pela proximidade com a Bahia de Todos os Santos.

Você sabia que nos tempos antigos, durante o tráfico de escravos nesta cidade, os filhos de Oduduwa usavam a mesma linguagem para se comunicarem?

Você sabia que se eles eram chamados de "Anago" ou "Nago", porque a língua que eles usam também se chamava "Anago" ou "Nago"?

É importante conhecer um pouco da história do povo Nagô nesta cidade.

 Isso porque será útil conhecer a história dos negos que vivem nesta cidade.

 Por esse motivo, vou dividir este tópico em três partes.

1. Os muçulmanos Nagô e a política no tempo da escravidão

2. Os Comerciantes Nago;

3. As Religiões tradicionais Nagô: A Religião Orixá e o Culto aos Voduns Candomblé

Na próxima semana, estaremos falando sobre: Os muçulmanos Nagô e a política no tempo da escravidão. 

Atá a próxima!

Comentários

Postagens mais visitadas deste blog

O Clã Nagô-Vodun Sakpata-Azansù

A Primeira Cartilha de Liturgia Jeje Savalu do Candomblé da Bahia

A Liturgia Vodun e o Candomblé Jeje da Bahia